Orin 58
Yọ̀, ẹnyin onigbagbọ
Rejoice, all ye believers
- f Yọ̀, ẹnyin onigbagbọ,
Jẹ k’ imọlẹ nyin taǹ
Igba alẹ mbọ̀ tete,
Oru si fẹrẹ̀ de
Ọkọ iyawo dide
O fẹrẹ sunmọle
Dide, gbadura, ṣọra,
L’ oru n’ igbe y’o ta. - mp Ẹ bẹ fitila nyin wò,
F’ ororo sinu wọn;
Ẹ duro de ‘gbàla nyin
Ipari ‘ṣẹ aiye;
mf Awọn oluṣọ nwipe,
Ọkọ ‘yawo de tan;
Ẹ pade rẹ̀, b’ o ti mbọ̀,
Pẹlu orin iyìn. - cr Ẹnyin wundia mimo,
Gbe ohùn nyin soke
f Titi, n’nu orin ayọ̀
Pẹlu awọn Angẹl.
Onjẹ iyawo ṣe tan,
‘Lẹ̀kun na ṣi silẹ,
ff Dide arole ogo
Ọkọ iyawo mbọ̀. - mp Ẹnyin ti ẹ nfi suru
Rù agbelebu nyin,
f Ẹ o si jọba lailaí
‘Gbati ‘ponju ba tan.
Yi itẹ ogo Rẹ̀ ka
Ẹ o r’ Ọd’ agutan
Ẹ o f’ ade ogo nyin
Lelẹ̀ niwaju Rẹ̀. - mf Jesu, ‘Wọ ireti wa
F’ara Rẹ hàn fun wa;
‘Wọ Orùn t’ a ti nreti
Ràn s’ ori ilẹ wa
A gbe ọwọ wa s’okè,
Oluwa jẹ k’a ri
Ọjọ ‘rapada aiye
T’ o mu wa d’ ọdọ Rẹ. Amin.