Skip to content
Iwe Orin Mimo

Orin 574

Ọrọ alafia

With the sweet word of peace

Meter 6.6.8.4 Fun awon ti o wa ninu oko
  1. mp Ọrọ alafia,
    La fi sìn nyin, ará,
    cr K’ alafia bi odo nla,
    Ma ba nyin lọ.

  2. mp N’nu ọ̀rọ adura,
    A f’ awọn ará wa
    Le iṣọ́ Oluwa lọwọ,
    Ọrẹ́ totọ.

  3. mf Ọrọ ifẹ didùn,
    L’a fi p’ odigboṣe;
    Ifẹ wa ati t’ Ọlọrun,
    Y’o ba wọn gbe.

  4. f Ọrọ gbagbọ lile,
    Ni igbẹkẹle wa;
    Pe, Oluwa y’o ṣe ranwọ,
    Nigba gbogbo.

  5. Ọrọ ‘reti didun,
    Y’o mu ‘pinyà wa dùn;
    Y’o sọ ayọ̀ t’o lè dùn jù
    Ayọ t’ aiye.

  6. mf Odigboṣe, ará,
    N’ ifẹ at’ igbagbọ;
    p Tit’ ao fi tun pade lokè,
    N’ il wa ọrun. Amin.