Orin 569
Iṣẹ gbogbo ti awa nṣe
God doth see all the work we do
- mf Iṣẹ gbogbo ti awa nṣe,
Ni Ọlọrun ti ri;
Erò gbogbo t’o wà ninu,
Ni Ọlọrun si mọ̀. - mp A kò le f’ẹṣẹ wa pamọ,
Gbogbo wọn l’O ti mọ̀:
A npurọ, a ntàn ‘ra wa jẹ,
B’ a rò pe kò mọ̀ wọn. - Ohun gbogbo hàn ni gbangba,
Ni oju Ọlọrun;
Okunkun ati imọlẹ,
Si ri bakanna fun. - f Ọlọrun, jẹ k’a ranti pe,
Oju rẹ si ri wa;
Si jẹ ke awa k’o bẹ̀ru
Lati dẹṣẹ si Ọ. Amin.