Skip to content
Iwe Orin Mimo

Orin 564

L’okọ Jesu, gbogbo ekun yio wolẹ̀

At the name of Jesus, every knee shall bow

Meter 11.11.11.11 Iyin
  1. mf L’okọ Jesu, gbogbo ekun yio wolẹ̀,
    Ahọn yio jẹwọ Rẹ̀ pe On l’Ọba ogo;
    Ifẹ Baba ni pe, k’a pe l’ Oluwa,
    cr Ẹnit’ iṣe Ọ̀rọ lat’ aiyeraiye.

  2. f Nipa Ọrọ Rẹ̀ l’a dá ohun gbogbo,
    Awọn angẹli at’ awọn imolẹ,
    Itẹ, ijoba, at’ awọn irawọ,
    Gbogbo ẹda ọrun ninu ogun wọn.

  3. p O rẹ̀ ‘ra Rẹ̀ silẹ, lati gb’ orukọ,
    Lọdọ awọn ẹlẹṣẹ t’o wa ku fun;
    cr Ko jẹ ki ẹ̀gàn bà lé orukọ yi,
    Titi O fi jinde t’a si ṣe l’ogo.

  4. mf Orukọ yi lo f’ayọ gbe lọ s’ọrun,
    cr Kọja gbogbo ẹda lọ sibi giga,
    f S’ itẹ Ọlọrun, ọ’okan aiya Baba,
    O si fi ogo isimi pipe kun.

  5. f F’ ifẹ darukọ Rẹ̀, ẹnyin ará, wa
    p Pẹlu ẹ̀ru jẹ̀jẹ̀ ati iyanu,
    mf Ọlọrun Oluwa, Krist, Olugbala,
    cr Titi lao ma sin Ọ, ao ma tẹriba.

  6. mf Ẹ jẹ ki Jesu jọba n’nu ọkàn nyin;
    Y’o mu ohun buburu gbogbo kuro;
    cr Ṣe l’ ọgagun nyin l’akoko idanwò;
    Ẹ jẹ ki ‘fẹ Rẹ̀ jẹ odi yi nyin ka.

  7. f Arakunrin, Jesu yi yio tun padà,
    N’nu ogo Baba, pẹl’ awọn angẹli;
    ff Gbogbo orilẹ-ede y’o wárí fun,
    Ọkàn wa y’o jẹwọ pe, On ni Ọba. Amin.