Orin 555
N’nu gbogbo ayida aiye
Through all the changing scenes of life
- mf N’nu gbogbo ayida aiye,
Ayọ on wahala;
cr Iyin Ọlọrun ni y’o ma
Wà l’ẹnu mi titi. - f Gbe Oluwa ga pẹlu mi,
Ba mi gb’Okọ Rẹ̀ ga;
p N’nu wahala, ‘gbà mo kepe,
cr O si yọ mi kuro. - f Ogun Ọlọrun wà yika
Ibugbe olotọ;
Ẹniti o ba gbẹkẹle,
Yio si ri ‘gbàla. - mf Sá dán ifẹ Rẹ̀ wó lẹkan,
Gbana ‘wọ o mọ̀ pe,
Awọn t’o di otọ Rẹ̀ mú
Nikan l’ ẹniẹ’bùkún. - cr Ẹ bẹru Rẹ̀, ẹnyin mimọ,
Ẹru miràn kò si;
Sa jẹ ki ‘sìn Rẹ j’ayọ̀ nyin,
On y’o ma tọju nyin. Amin.