Orin 543
Fi Ibukun Rẹ tu wa ka
Lord, dismiss us with Thy blessing;
- mf Fi Ibukun Rẹ tu wa ka,
Fi ayọ kùn ọkàn wa;
K’ olukuluku mọ̀ ‘fẹ Rẹ,
K’a l’ayọ n’nu ore Rẹ:
Tù wa lara, tù wa lara
La aginju aiye ja. - f Ọpẹ at’ iyìn l’ a nfun Ọ,
Fun ihinrere ayọ̀;
mf Jẹ ki eso igbala Rẹ
Pọ̀ lọkàn at’ ìwa wa :
cr Ki oju Rẹ, ki oju Rẹ
Ma ba wa gbe titi lọ. - p Njẹ, nigbat’ a ba sì pe wa
Lati f’ aiye yi silẹ,
cr K’ Angẹli gbe wa lọ sọrun,
Layọ̀ ni k’a jipe na;
f K’a si jọba, k’a sì jọba
Pẹlu Kristi titi lai. Amin.