Orin 534
Wakati adurà didùn!
Sweet hour of prayer! sweet hour of prayer!
- f Wakati adurà didùn!
T’o gbe mi lọ kuro laiye,
L’ọ ‘waju itẹ Baba mi,
Ki nsọ gbogbo ẹ̀dun m fun;
cr Nigba ‘banujẹ at’ arò,
Adua l’ abò fun ọkàn mi;
Emi si bọ̀ lọwọ Eṣu,
‘Gbati mo ba gb’ adua didùn,
Emi si bọ́ lọwọ Eṣu,
‘Gbati mo ba gb’ adua didun. - f Wakati adurà didùn !
Iyẹ rẹ y’o gbe ẹ̀bẹ mi
Lọ sọd’ Ẹnit’ o ṣeleri
Lati bukun ọkàn adua:
B’ O ti kọ́ mi, ki nw’ oju Rẹ̀,
Ki ngbẹkẹle, ki nsi gba gbọ:
Ngo kó gbogb` aniyan mi le,
Ni akoko adua didùn.
Ngo kó gbogb` aniyan mi le,
Ni akoko adua didùn. - Wakati adurà didùn !
Jẹ ki nma r’itunu rẹ gbà,
Titi ngo fi d’oke Pisga,
Ti ngo r’ile mi l’okere.
Ngo bọ́ agọ ara silẹ,
Ngo gbà ère ainipẹkun;
f Ngo kọrin bi mo ti nfò lọ,
cr Odigboṣe ! adua didùn.
f Ngo kọrin bi mo ti nfò lọ,
cr Odigboṣe ! adua didùn. Amin.