Orin 53
Oluwa agbara fọhùn
The Lord of might, from Sinai’s brow
- f Oluwa agbara fọhùn,
Bi ará l’oke Sinai;
Awọn Israeli gbohùn Rẹ̀,
Nwọn si gbọ̀n fun iberu:
Okunkun ṣú biribiri;
Ati l’ọtun ati l’osì,
ff Awọn apata nfaya. - p Oluwa ifẹ jẹ ‘rora
L’ori oke Kalfari;
O gbe oju soke ọrun,
L’ akoko wahala Rẹ̀:
Fun wa l’o rù ẹrù egbé,
Fun wa l’o t’ ẹjẹ Rẹ̀ silẹ,
T’ o si tù Baba l’oju. - mf Ọba ifẹ at’ agbara,
Oluwa ẹda gbogbo
cr O npada bọ ninu ogo,
Lati wa gba ijọba;
ff Ipè y’o dùn, angẹl y’o hó,
Halleluya y’o j’orin wọn
L’ ori Eṣu ati’ iku. Amin.