Orin 529
Jesu Oluwa ni ‘ṣe
The church’s one foundation
- f Jesu Oluwa ni ‘ṣe
Ipilẹ Ijọ Rẹ̀ ;
Omi ati ọrọ̀ Rẹ̀,
Ni On sì fi tun da;
di O t’ ọrun wa, O fi ṣe
Iyawo mimọ Rẹ̀;
p Ẹjẹ Rẹ̀ l’O si fi ra,
Ti O si ku fun u. - mf N’ilẹ gbogbo l’a ṣà wọn,
Ṣugbọn nwọn jẹ ọ̀kan;
Oluwa kan, ‘gbagbọ kan,
Ati baptisi kan;
Orukọ kan ni nwọn nyìn,
Onjẹ kan ni nwọn njẹ;
Opin kan ni nwọn nlepa,
Nipa ore-ọfẹ. - mp Bi aiye tilẹe nkẹgàn,
Gbat’ iyọnu de ba;
B’ija on ẹkọ́-kẹ-kọ
Ba mu iyapa wa;
cr Awọn mimọ y’o ma ke
Wipe, “Y’o ti pẹ to?”
p Oru ẹkun fẹrẹ̀ di
f Orọ̀ orin ayọ̀. - mf L’arin gbogbo ‘banujẹ,
At’ iyọnu aiye,
O nreti ọjọ ‘kẹhìn
Alafia lailai;
cr Titi y’o f’oju rẹ̀ ri,
Iran ologo na,
f Ti ijọ nla aṣẹgun,
p Y’o d’ijọ ti nsimi. - mf L’aiye, yi o ni ‘dapọ̀
Pẹlu Mẹtalọkan !
p O sì ni ‘dapọ̀ didùn
Pẹl’ awọn t’o ti sùn;
cr A ! alabukun mimọ́!
Oluwa, fi fun wa,
K’ a ba le ri bi awọn,
f K’ a ba Ọ gbe l’ọrun. Amin.