Orin 520
Awọn mimọ, lala pari
The saints of God! their conflict past
- mf Awọn mimọ, lala pari,
Nwọn ti jà, nwọn si ti ṣẹgun,
Nwọn kò fẹ ohun ìja mọ,
Nwọn dà wọn ‘lẹ̀ l’ ẹsẹ Jesu:
cr A ! ẹnyin ẹni ibukun,
p Isimi nyin ti daju to ! - mf Awọn mimọ, ìrin pari,
Nwọn kò tun sure ije mọ,
Arẹ at’ iṣubu d’ opin,
Ọtá on ẹ̀ru kò sí mọ:
cr A ! ẹnyin ẹni ibukun,
p Isimi nyin ti daju to ! - mf Awọn mimọ, àjo pari,
Nwọn ti gún s’ ilẹ ibukun,
Iji kò dẹruba wọn mọ,
Igbi omi kò n’ ipá mọ;
cr A ! ẹnyin ẹni ibukun,
p Isimi nyin ti daju to ! - Awọn mimọ, oku wọn sùn
Ninu ilẹ, awọn nṣọnà
cr Titi nwọn yio fi jinde,
Lati fi ayọ goke lọ:
f A ! ẹni ‘bukun, ẹ kọrin;
Oluwa at’ Ọba nyin mbọ̀. - mf Ọlọrun wọn, ‘Wọ l’a nkepè,
Jesu, bẹ̀bẹ fun wa l’ oke;
Ẹmi Mimọm Olutọ́ wa,
p F’ ore-ọfẹ fun wa d’ opin;
cr K’a le b’ awọn mimọ simi,
f Ni Paradise pẹlu Rẹ. Amin.