Orin 516
Igba aṣalẹ ti dùn to !
How sweet the hour of closing day
- mp Igba aṣalẹ ti dùn to !
Ti ara tù ohun gbogbo:
‘Gbat’ ìtanṣan orùn alẹ
Ba ntànmọlẹ s’ ohun gbogbo! - Bẹni ‘kẹhìn onigbagbọ,
On a simi l’ alafia;
cr Igbagbọ to gbona janjan
A mọlẹ ninu ọkàn rẹ̀. - mf Imọlẹ kan mọ loju rẹ̀,
Ẹrin sì bọ ni ẹnu rẹ̀;
O nf’ ède t’ ahọn wa kò mọ̀
Sọ̀rọ ogo t’o sunmọle. - cr Itanṣan ‘mọlẹ t’ ọrun wá,
Lati gba niyanju lọna;
Awọn angẹl duro yika
Lati gbe lọ s’ibugbe wọn. - mp Oluwa, jẹ k’ a lọ bayi,
K’a ba Ọ yọ̀, k’a r’ oju Rẹ;
cr Tẹ̀ aworan Rẹ s’ ọkàn wa,
Si kọ́ wa b’ a ti ba Ọ rìn. Amin.