Orin 508
A fẹ ri Jesu, ‘tori ojiji wa ngùn
We would see Jesus; for the shadows lengthen
- mp A fẹ ri Jesu, ‘tori ojiji wa ngùn,
Ojiji igba ọjọ aiye wa;
A fẹ ri Jesu, k’O busi gbàgbọ wa,
Nigbà akókò titan wa ba de. - A fẹ ri Jesu, arẹ nmu ọkàn wa,
A fẹ ri I, arẹ nmu ara wa;
Igbì iyọnu pupọ̀ l’o ti nlù wa,
Igbì mi sì tun ndide tọ wa bọ̀. - cr A fẹ ri Jesu, Apata ‘pilẹ̀ wa,
Li ori eyiti a duro le;
f Iyè, iku, gbogbo wahala aiye,
Kò lè y’ ẹsẹ̀ wa, b’ a ba roju Rẹ̀. - mp A fẹ ri Jesu, aiye kò l’adùn mọ.
Ohun t’a nyọ̀ si ri ṣá l’oju wa,
di Awọn ọrẹ́ wa gbogbo l’o ti nkọja lọ,
cr Ao kẹdùn wọn mọ, ṣe awa na mbọ̀. - p A fẹ ri Jesu, ṣugbọn oju nro wa,
Nitori awọn ará at’ ọrẹ́;
Ara wa pẹlu kò fẹ f’aiye silẹ̀,
Ifẹ wa si Ọ kò mu ‘fẹ yi dinkù. - p A fẹ ri Jesu, oju ọkàn wa fọ́,
Ọrun ṣú, o sì jinà loju wa;
cr A fẹ ri Ọ, O rán ọkàn wa leti
Iyà t’O jẹ lati san gbeṣe wa. - f A fẹ ri Jesu, eyi l’ohun t’a fẹ,
Gbà t’a ba ri Ọ, ayọ̀ nla y’o de;
‘Wọ t’Oku, t’O jinde, t’O mbẹ̀bẹ̀ fun wa,
ff ‘Gbana, ‘mọlẹ y’o de, okùn y’o si lọ. Amin.