Orin 500
Ọjọ nla l’ ọjọ́ ti o yàn
Oh happy day, that fixed my choice
- f Ọjọ nla l’ ọjọ́ ti o yàn
Olugbala l’Ọlọrun mi:
O yẹ ki ọkàn mi ma yọ̀,
K’o sì ro ìhin na ká ‘lẹ̀.
f Ọjọ nla l’ ọjọ na!
p Ti Jesu wẹ̀ ẹ̀ṣẹ mi nù;
O kọ mi ki mma gbadura,
Ki mma ṣọra, ki nsì ma yọ̀,
Ọjọ nla l’ ọjọ na!
Ti Jesu wẹ̀ ẹ̀ṣẹ mi nù. - Iṣẹ ìgbala pari na,
Mo di t’ Oluwa mi loni;
On l’o pè mi ti mo sì jẹ́,
Mo f’ ayọ̀ jipè mimọ ná.
f Ọjọ nla, &c. - Ẹjẹ́ mimọ yi ni mo jẹ́
F’ Ẹnit’ o yẹ lati fẹràn;
Jẹ k’ orin didùn kún ‘le Rẹ̀,
Nigba mo ba nlọ sìn nibẹ.
f Ọjọ nla, &c. - Simi, aiduro ọkàn mi,
Simi le Jesu Oluwa;
Tani jẹ wipe aiye dùn
Jù ọ̀dọ awọn Angẹli?
f Ọjọ nla, &c. - Ẹnyin ọrun, gbọ ẹ̀jẹ́ mi;
Ẹjẹ́ mi ni ojojumọ,
Em’ o ma sọ dọtun titi
Iku y’o fi mu mi re ‘le.
f Ọjọ nla, &c. Amin.