Orin 498
Mo ti ṣeleri, Jesu
O Jesus, I have promised
- mf Mo ti ṣeleri, Jesu,
Lati sìn Ọ dopin;
Ma wà lọdọ mi titi,
Baba mi, Ọrẹ́ mi,
Emi k’yo bẹru ogun,
B’ iwọ ba sunmọ mi,
Emi kì y’o si ṣina,
B’o ba f’ọna hàn mi. - Jẹ ki mmọ̀ p’ o sunmọ mi,
‘Tor’ibajẹ aiye;
Aiye fẹ gbà ọkàn mi,
Aiye fẹ tàn mi jẹ;
di Ọta yi mi ka kiri,
Lode ati ninu;
cr Ṣugbọn Jesu, sunmọ mi,
Dabobo ọkàn mi. - p Jẹ ki emi k’o ma gbọ́
Ohùn Rẹ, Jesu mi,
Ninu igbi aiye yi,
Titi nigbagbogbo;
cr Sọ, mu k’o dá mi l’oju,
K’ ọkàn mi ni ‘janu;
Sọ, si mu mi gbọ Tirẹ,
‘Wọ olutoju mi. - mf ‘Wọ ti ṣe ‘leri, Jesu,
F’ awọn t’o tẹ̀le Ọ,
Pe ibikibi t’ O wà,
L’awọn yio si wà;
Mo ti ṣe ‘leri, Jesu,
Lati sìn Ọ dopin,
Jẹ ki nma tọ Ọ lẹhin,
Baba mi, Ọrẹ́ mi. - p Jẹ ki nma ri ‘pasẹ Rẹ,
Ki nlè ma tẹlé Ọ:
Agbara Rẹ nikan ni,
Ti mba lè tẹlé Ọ,
Tọ́ mi, pè mi, sì fà mi,
Di mi mu de opin;
Si gba mi si ọdọ Rẹ.
Baba mi, Ọrẹ́ mi. Amin.