Orin 491
Máṣe huwa ẹ̀ṣẹ
Do no sinful action
- mf Máṣe huwa ẹ̀ṣẹ,
Má sọ̀rọ ‘binu;
Ọmọ Jesu l’ ẹ ṣe,
Ọmọ Oluwa. - mf Krist jẹ oninure,
At’ ẹni mimọ́;
Bẹ l’ awọn ọmọ Rè
Yẹ k’o jẹ mimọ́. - p Ẹmi ibi kan wà,
T’ o nṣọ ìrin rẹ;
O si nfẹ dan ọ wò,
Lati ṣe ibi. - Ẹ má ṣe gbọ́ tirẹ̀.
B’ o tilẹ̀ ṣoro
Lati ba Eṣu jà,
Lati ṣe rere. - mf Ẹnyin ti ṣe ‘leri
Ni ọmọ-ọwọ,
Lati k’ Eṣu silẹ,
Ati ọ̀na rẹ̀. - Ọm’ ogun Krist ni nyin,
Ẹ kọ́ lati bá
Ẹṣẹ inu nyin jà;
Ẹ ma ṣe rere. - f Jesu l’Oluwa nyin,
cr O ṣe ẹnire;
Ki ẹnyin ọmọ Rẹ̀
Si ma ṣe rere. Amin.