Orin 49
Iwọ mbọ̀ wá, Oluwa mi
Thou art coming, O my Saviour,
- f Iwọ mbọ̀ wá, Oluwa mi,
Iwọ bọ wá, Ọba mi,
cr Ninu ìtansan ẹ̀wa Rẹ;
Ninu titayọ ogo Rẹ;
O yẹ k’a yọ̀, k’a kọrin !
p.cr O mbọ̀; -- ni ìla-orun
Awọn akede npọ̀ si;
p.cr O mbọ̀: -- Alufa ogo;
A ko ha ngbọ ago Rẹ? - f Iwọ mbọ̀ wá, Iwọ mbọ̀ wá
A o pade Rẹ lọnà;
cr A o ri Ọ, a o mọ̀ Ọ,
A o yin Ọ; gbogbo ọkàn
L’a o ṣipaya fun Ọ:
f Orin kil’ eyi o jẹ!
Orin t’o dùn rekọja:
A o tu ‘fẹ wa jade
Si ẹsẹ̀ Rẹ Ologo. - mf Iwo mbọ wà; ni tabil’ Rẹ,
L’ awa njeri si eyi;
p T’a mọ̀ p’ O npade ọkàn wa
Ni ìdapọ mimọ́ julọ;
Ẹri ibukun ti mbọ,
cr Kò f’ iku Rẹ nikan hàn,
At’ ifẹ titobi Rẹ,
Ṣugbọn bibò Rẹ pẹlu
T’a nfẹ, t’a si nduro dè. - f Y’o dùn lati ri Ọ njọba
Oluwa mi Olufẹ;
cr Ki gbogbo ahọn jẹwọ Rẹ;
Iyin, ọla, ati ogo,
Ki nwọn jumọ fi fun Ọ:
ff ‘Wọ, Ọga mi, Ọrẹ mi,
K’o ṣẹgun, k’ o si gunwa,
Titi de opin aiye,
Ninu ogo at’ ọla. Amin.