Orin 483
Ọlọrun, orin ẹniti
Almighty God, theme of the song
- f Ọlọrun, orin ẹniti
Awọn Angẹli nkọ;
Wò ‘lẹ̀ lati bujoko Rẹ!
Kọ wa, k’a bẹ̀ru Rẹ! - Ọrọ mimọ́ Rẹ l’ a fẹ kọ́,
Lat’ igba ewe wa;
K’ a kọ t’ Olugbala t’ iṣe
Ọna, Iye, Otọ. - Jesu, ogo at’ ore Rẹe,
L’ a nsọ nisisiyi;
Ṣe bujoko Rẹ s’ ọkàn wa,
Si jẹ k’ a bẹ̀ru Rẹ. Amin.