Orin 468
Ọrẹ kan mbẹ fun ọmọde
There's a Friend for little children
- mf Ọrẹ kan mbẹ fun ọmọde
Loke ọrun lọhun;
Ọrẹ ti ki yipada,
T’ ifẹ rẹ̀ kò le ku;
p Kò dabi ọrẹ aiye,
Ti mbajẹ lọdọdun;
f Orukọ Rẹ̀ bi ọrẹ
Wọ fun nigbagbogbo. - mp Isimi kan mbẹ f’ọmọde
Loke ọrun lọhun;
F’awọn t’o f’ Olugbala,
Ti nke “Abba Baba:”
di Isimi lọwọ ‘yọnu;
Lọw’ ẹ̀ṣẹ at’ ewu;
p Nibit’ awọn ọmọde
Y’o simi titi lai. - mf Ile kan mbẹ fun ọmọde,
Loke ọrun lọhun;
f Nibiti Jesu njọba,
Ile alafia !
di Kò s’ile t’o jọ laiye
T’a le fi ṣàkawé:
f Ara rọ ‘lukulukù;
Irọra na dopin. - cr Ade kan mbẹ fun ọmọde
Loke ọrun lọhun;
Ẹnit’o ba nwò Jesu
Y’o ri ade na de:
Ade t’o logo julọ,
Ti y’o fi fun gbogbo
mf Awọn ọrẹ rẹ̀ laiye;
Awọn t’o fẹ nihin. - f Orin kan mbẹ fun ọmọde
Loke ọrun lọhun;
Orin ti kò le su ni,
B’o ti wù k’a kọ to!
mf Orin t’awọn angẹli
Kò le ri kọ titi;
Krist ki ṣ’Olugbala wọn,
Ọba l’o jẹ fun wọn. - f Ẹwu kan mbẹ fùn ọmọde
Loke ọrun lọhun;
Harpu olohùn didùn !
Imọpẹ iṣẹgun !
Gbogbo ẹ̀bun rere yi
L’a ni ninu Jesu;
p Ẹ wá, ẹnyin ọmọde,
Ki nwọn le jẹ ti yin. Amin.