Orin 466
Gbat’ O ba de, gbat’ O ba de
When he cometh, when he cometh
- mf Gbat’ O ba de, gbat’ O ba de,
Lati ṣir` ọ̀ṣọ́ Rẹ̀;
Gbogb’ ọ̀ṣọ́ Rẹ̀ iyebiye,
Awọn ti O fẹ!
f Bi ìrawọ owurọ, nwọn nṣ’ade Rẹ̀ lọṣọ,
Ẹwà wọn o yọ pupọ̀, ẹwà f’ade Rẹ̀. - Yio kójọ, yio kójọ,
Ọṣọ́ ijọba Rẹ̀;
Awọn mimọ, awọn dídán,
Awọn ti O fẹ.
f Bi irawọ, &c. - Awọn ewe, awọn ewe
T’o fẹ Olugbala;
Ni ọ̀ṣọ́ Rẹ̀ iyebiye,
Awọn ti Ò fẹ.
f Bi ìrawọ owurọ, nwọn nṣ’ade Rẹ̀ lọṣọ,
Ẹwà wọn o yọ pupọ̀, ẹwà f’ade Rẹ̀. Amin.