Orin 461
Ọpọ íkán omi
Little drops of water
- mf Ọpọ íkán omi,
Yanrin kekeke;
cr Wọnyi l’o f’okun nla,
At’ ilẹ̀ẹaiye. - mp Iṣẹju wa kọkan,
Ti a kò kàsi,
cr L’ o nd’ ọdun aimoye
Ti ainipẹkun. - mp Iwa ore diẹ,
Ọrọ̀ ‘fẹ diẹ,
cr L’ o ns’ aiye di Eden,
Bi oke ọrun. - p Iṣìṣe kekeke
L´o nmọkàn ṣìna,
Kuro l` ọ̀na rere,
Si ipa ẹ̀ṣẹ. - mf Iṣẹ anu diẹ
T’a ṣe l’ọmọde,
cr Di ‘bukun f’orilẹ
T’o jina réré. - f Awọn ewe l’ogo
Ngberin Angẹli;
di Ṣe wa yẹ Oluwa
p F’ẹgbẹ mimọ́ wọn. Amin.