Orin 451
Wò b’Oluṣagutan Israel
See Israel’s gentle shepherd stand
- mf Wò b’Oluṣagutan Israel
Ti fi ayọ̀ duro;
Lati gb’awọn Ọd’ agutan,
K’o si kó wọn mọra. - On si wi pe, “Jẹ ki nwọn wa.”
p “Ẹ maṣe kẹgan wọn;”
Lati sure fun ìru wọn,
L’Ọba Angẹl ṣe wa. - Pẹlu ọpẹ l’ a gbe wọn wa,
A jọwọ wọn fun Ọ;
A yọ̀; bi a ti jẹ Tirẹ,
K’ọmọ wa jẹ Tirẹ. - Ẹ mà yọ̀; ọdọ agutàn,
K’ẹ ma ṣafẹri Rẹ̀;
Pẹlu ayọ̀ ni k’ẹ sunmọ,
K’o le sure fun nyin. - Bi a ba fi wọn s’aiye lọ,
‘Wọ to Baba fun wọn;
Bi nwọn si ku ni ọwọ wa,
Tù wa ninu, Jesu. Amin.