Orin 45
Wá, ẹnyin ọlọpe, wá
Come, ye thankful people, come,
- f Wá, ẹnyin ọlọpe, wá,
Gbe orin ikore ga;
Irè gbogbo ti wọle
K’ otutu ọyẹ to de;
mf Ọlọrun Ẹlẹda wa
L’o ti pèse f’ aini wa;
ff Wa k’a re ‘le Ọlọrun
Gbe orin ikore ga. - mf Oko Ọlọrun l‘ aiye,
Lati s’ eso iyìn Re;
Alikama at’èpo
Ndagba t’ arò tab’ ayọ̀:
cr Ehu na, ìpẹ́ tele,
Ṣiri ọka nikẹhin;
p Oluwa ‘kore, mu wa
Jẹ eso rere fun Ọ. - mf N’tori Ọlọrun wa mbọ̀.
Y’o si kore Rẹ̀ sile;
On o gbọ̀m gbogbo pànti
Kuró l’oko Rẹ̀ n’jọ na:
p Y’o t’ aṣẹ f’awọn Angẹl’
Lati gbá èpo s’iná,
f Lati kó alikama
Si abà Rẹ̀ titi lai. - f Bẹni, ma wá, Oluwa
Si ikore ikẹhìn;
Ko awọn enia Rẹ jọ
Kuro l’ẹṣẹ at’ arò:
cr Sọ wọn di mimọ lailai
Ki nwọn le mà ba Ọ gbe:
ff Wà t’ Iwọ t’ Angẹli Re
Gbe orin ikore ga. Amin.