Orin 447
Duro, ọmọ ogun
Stand, soldier of the cross
- f Duro, ọmọ ogun,
F’ ẹnu rẹ sọ f’aiye;
Si jẹjẹ pe òfo l’aiye,
Nitori Jesu rẹ. - f Dide, k’a baptis’ rẹ,
K’ o wẹ ẹ̀ṣẹ rẹ nù,
Wá b’ Ọlọrun dá majẹmu,
Sọ ‘gbagbọ rẹ loni. - Tirẹ ni Oluwa,
At’ ijọba ọrun;
Sa gb’ àmi yi siwaju rẹ,
Ami Oluwa rẹ. - ‘Wọ k’ iṣe t’ ara rẹ,
Bikoṣe ti Kristi;
A kọ orukọ rẹ pọ̀ mo
Awọn mimọ́ gbani. - Ni hamọra Jesu,
Kọjuja si Eṣu;
B’o ti wù k’ ogun na le to,
Iwọ ni o ṣẹgun. - Ade didara ni,
Orin na, didun ni,
‘gba t’a ba ko ikogun jọ
S’ ẹsẹ̀ Olugbala. Amin.