Orin 424
Baba, niwaju itẹ Rẹ
Father, before Thy throne of light
- f Baba, niwaju itẹ Rẹ,
L’angẹli ntẹriba;
Nigbagbogbo niwaju Rẹ,
Ni nwọn nkọrin iyìn;
di Nwọn si nfi ade wura wọn,
Lelẹ yitẹ na ka;
cr Nwọn nfi ohùn pẹlu duru
Kọrin si Oluwa. - mf Didan Oṣumare si nstàn
Si ara iyẹ wọnn;
cr Bi Seraf ti nke si Seraf,
Ti nwọn nkọrin ‘yin Rẹ;
p Bi a ti kunlẹ nihinyi,
Ran ore Rẹ si wa;
K’a mọ̀ pe ‘Wọ wà nitosi,
Lati da wa lohùn. - mf Nihin, nibit’ awọn Angẹl
Nwò wa b’a ti nsin Ọ;
cr Kọ́ wa k’a wá ile ọrun,
K’a sin Ọ bi ti wọn;
f K’a ba wọn kọ orin iyin,
K’a ba wọn mo ‘fẹ Rẹ;
Titi agbara y’o fi di
Tirẹ, Tirẹ nikan. Amin.