Orin 415
Tal’awọn wọnyin t’irawọ
Who are these like stars appearing
- f Tal’awọn wọnyin t’irawọ,
Niwaju itẹ mimọ,
Ti nwọn si de ade wura,
Ẹgbẹ ogo wo l’eyi?
ff Gbọ́! Nwọn nkọ Alleluya,
Orin iyìn Ọba wọn! - mf Tali awọn ti nkọ màna,
T’a wọ̀ l’aṣọ ododo?
Awọn ti aṣọ funfun wọn
Y’o ma funfun titi lai,
Bẹni ki y’o gbó lailai:
Nibo l’ẹgbẹ yi ti wa? - p Awọn wọnyi l’o ti jagun,
F’ọla Olugbala wọn;
Nwọn jijakadi tit’ ikú,
Nwọn kì b’ẹlẹṣẹ kẹgbẹ:
cr Wọnyi ni kò sá f’ogun,
f Nwọn ṣẹgun nipa Kristi. - p Wọnyi l’ọkàn wọn ti gbọgbẹ,
Ninu danwo kikorò;
Wọnyi li o ti f’ adura,
Mu Ọlọrun gbọ́ tiwọn;
cr Nisisiyi nwọn ṣẹgun,
Ọlọrun rẹ̀ wọn l’ẹkun. - mf Awọn wọnyi l’o ti ṣọra,
Ti nwọn fi ifẹ wọn fun Krist;
Nwọn si y’ ara wọn si mimọ́,
Lati sìn nigbagbogbo;
f Nisisiyi li ọrun,
Nwọn wà l’ ayọ̀ l’ọdọ Rẹ̀. Amin.