Orin 411
“Wa sọdọ mi, alarẹ̀
Come unto Me, ye weary
- mf “Wa sọdọ mi, alarẹ̀,
Ngo fun nyin n’isimi,”
p A ! ohùn didun Jesu,
Ti o p’ẹlẹṣẹ wá.
cr O nsọ ti ore-ọfẹ,
Ati t’alafia,
Ti ayọ̀ ti kò lopin,
T’ ifẹ ti kò le tàn. - mf “Ẹ wá, ẹnyin ọmọ Mi,
Ngo fun nyin n’ imọlẹ”
p A! ohun ifẹ Jesu,
cr Ti nle okunkun lọ;
p Awa kun fun banujẹ,
A ti s’ọ̀na wa nù;
f Imọlẹ y’o m’ayọ̀ wà,
Orọ y’o m’ orin wá. - mf “Ẹ wà, ẹnyin ti ndàku,
Ngo fun nyin ni iyè:”
p Ohùn alafia Jesu,
T’ o f’opin s’ija wa.
mf Oju ọta wa korò,
Ija si le pupọ;
cr Ṣugbọn ‘Wọ fun wa n’ipá,
f A bori ọta wa. - mf “Ẹnikẹni t’o ba wá,
Emi ki o ta nù;”
p A! ohùn suru Jesu,
cr T’o le ‘yemejì lọ!
mf Ninu ifẹ iyanu,
T’o p’ awa ẹlẹṣẹ,
B’a tilẹ jẹ alaiye,
S’ọdọ Rẹ, Oluwa. Amin.