Orin 395
Kọ mi Oluwa, bi a ti
Lord, speak to me, that I may speak
- mf Kọ mi Oluwa, bi a ti
Jẹ gbohungbohun ọ̀rọ Rẹ;
B’ o ti wá mi, jẹ k’emi wá
Awọn ọmọ Rẹ t’o ti nù. - Tọ mi Oluwa, ki nle tọ́
Awọn aṣako si ọnà;
Bọ́ mi Oluwa, ki nle fi
Manna Rẹ b’ awọn t’ ebi npa. - f Fun mi l’agbara; fi ẹsẹ
Mi mulẹ̀ lori apata;
di Ki nlè na ọwọ igbala
S’ awọn t’o nrì sinu ẹ̀ṣẹ. - mf Kọ mi Oluwa, ki nlè fi
Ẹkọ rere Rẹ k’ẹlomi;
F’iyẹ f’ọrọ mi, ko le fò
De ikọkọ gbogbo ọkan. - f F’ isimi ‘didun Rẹ fun mi,
Ki nlè mọ̀, b’o ti yẹ lati
Fi pẹlẹpẹlẹ s’ọrọ Rẹ
Fun awọn ti arẹ̀ ti mu. - f Jesu, fi ẹkún Rẹ kùn mi,
Fi kùn mi li ọpọlọpọ;
Ki erò ati ọ̀rọ mi
Kùn fun ifẹ at’ iyin Rẹ. - cr Lò mi, Oluwa, an’ emi,
Bi o ti fe, nigbakugba;
ff Titi em’ o fi r’ oju Rẹ.
Ti ngo pin ninu ogo Rẹ. Amin.