Orin 392
Tan ‘mọlẹ Rẹ si wa
Shine Thou upon us, Lord
- mf Tan ‘mọlẹ Rẹ si wa
Loni yi Oluwa;
Fi ara Rẹ hàn wa
N’nu ọrọ Mimọ Rẹ;
Jọ m’ọkan wa gbona,
K’ a ma wo oju Rẹ,
K’ awọn ‘mọde le kọ
Iyanu ore Rẹ. - mp Mí si wa Oluwa,
Ina Ẹmi Mimọ,
cr K’a le fi ọkàn kan
Gbe orukọ Rẹ ga;
Jọ fi eti igbọ,
At’ ọkàn ironu,
Fun awọn ti a nkọ,
L’ ohun nla t’O ti ṣe. - mf Ba ni sọ, Oluwa,
Ohun to yẹ k’a sọ,
Gẹgẹ bi ọrọ Rẹ,
Ni ki ẹkọ wa jẹ;
K’awọn agutan Rẹ,
Le ma mọ ohùn Rẹ,
Ibit’ O ntọ́ wọn si,
cr Ki nwọn ọiọ le ma yọ̀. - mf Gbe ‘nu wa, Oluwa,
K’ifẹ Rẹ je tiwa,
Iwọ nikan lao fi
Ipa wa gbogbo sin;
K’iwa wa jẹ ẹkọ.
Fun awọn ọmọ Rẹ,
di K’o si ma kede Rẹ,
Ninu gbogbo ọkàn. Amin.