Orin 375
Ha! ẹgbẹ mi, ẹ w’asia
Ho! my comrades, see the signal,
- f Ha! ẹgbẹ mi, ẹ w’asia
Bi ti nfẹ lẹlẹ!
Ogun Jesu fẹrẹ de na,
A fẹrẹ̀ ẹgun!
ff “D’ odi mu, emi fẹrẹ̀ de,”
Bẹni Jesu nwi,
Ràn ‘dahun pada s’ọrun, pe,
Awa o dimu. - f Wò ọpọ ogun ti mbọ̀ wa,
Eṣu nkó wọn bọ̀;
Awọn alagbara nṣubu,
p A fẹ damu tan!
ff D’odi mu, &c. - Wò asia Jesu ti nfẹ;
Gbọ́ ohun ipẹ̀;
A o ṣẹgun gbogbo ọta
Ni oruko Rẹ̀.
ff D’odi mu, &c. - f Ogun ngbona girigiri,
Iranwọ wa mbọ̀;
Balogun wa mbọ̀ wa tete,
Ẹgbẹ, tujuka!
ff D’odi mu, &c. Amin.