Orin 373
Didan l’ọpagun wa, o ntoka s’ọrun
Brightly gleams our banner, Pointing to the sky
- f Didan l’ọpagun wa, o ntoka s’ọrun,
O nfọnahàn ogun, s’ile wọn ọrun!
Lar’n aginju l’a nrin, l’ ayọ̀ l’a ngbadura,
Pẹl’ọkàn iṣọkan l’a ‘m’ ọn’ ọrun pọ̀n.
Didan l’ọpagun wa, O ntọka s’ọrun,
O nfọnahàn ogun, s’ile wọn ọrun. - mf Jesu Oluwa wa, l’ẹsẹ Rẹ ọ̀wọ,
Pẹlu ọkàn ayọ̀ l’ọmọ Rẹ pade:
p A ti fi Ọ silẹ̀, a si ti ṣako,
Tọ́ wa Olugbala si ọnà toro.
Didan l’ọpagun wa, &c. - mf Tọ̀ wa l’ọjọ gbogbo, l’ọna t’awa ntọ̀,
Mu wa nṣo s’iṣẹgun l’ori ọta wa;
di K’ Angẹl Rẹ ṣ’asa wa gb’oju ọrun ṣú
p Dariji, si gba wa lakoko iku.
Didan l’ọpagun wa, &c. - f K’ a le pẹlu awọn Angẹli loke,
Lati jumọ ma yin n’itẹ ifẹ Rẹ:
cr ‘Gbat’ajo wa ba pin, isimi y’o de,
ff At’ alafia, at’ orin ailopín.
Didan l’ọpagun wa, &c. Amin.