Orin 353
Jesu, mo gb’ agbelebu mi
Jesus, I my cross have taken,
- mp Jesu, mo gb’ agbelebu mi,
Ki nle ma tọ̀ Ọ lẹhin;
p Otosi at’ ẹni ẹ̀gan,
mf ‘Wọ l’ ohun gbogbo fun mi:
Bi ìní mi gbogbo ṣegbe,
Ti èro mi gbogbo pin;
cr Sibẹ ọlọrọ̀ ni mo jẹ!
f Temi ni Krist’ at’ Ọrun. - p Ẹda le ma wahala mi,
cr Y’o mu mi sunmọ Ọ ni;
p Idanwo aiye le ba mi,
cr Ọrun o mu ‘simi wá.
mf Ibanujẹ kò le ṣe nka
B’ ifẹ Rẹ ba wà fun mi;
Ayọ̀, kò si le dùn mọ mi,
B’ Iwọ kò si ninu rẹ̀. - cr Ọkàn mi, gba igbala rẹ,
Bori ẹ̀ṣẹ at’ ẹ̀ru.
mf F’ ayọ̀ wà ni ipokipo,
Ma ṣiṣẹ, sì ma jìya:
mp Rò t’ Ẹmi t’o wà ninu rẹ:
At’ ifẹ Baba si Ọ;
W’ Olugbala t’o ku fun ọ;
cr Ọmọ ọrun, maṣe kùn! - ff Njẹ kọja lat’ ore s’ ogo,
N’n’ adurà on igbagbọ;
Ọjọ ailopin wà fun Ọ,
Baba y’o mu ọ de ‘bẹ.
di Iṣẹ rẹ laiye fẹrẹ pin,
Ọjọ àjo rẹ mbuṣe,
cr Ireti y’o pada s’ayọ̀.
f Adura s’orin iyìn. Amin.