Orin 340
Jesu Oluwa, Ọba mi
Jesu, my Lord, my God, my All
- mf Jesu Oluwa, Ọba mi,
Gbohùn mi nigbati mo npè,
Gbohùn mi lati ‘bugbe Rẹ,
Rọjo ore-ọfẹ silẹ;
cr Oluwa mi, mo fẹràn Rẹ,
Jẹ ki nle ma fẹràn Rẹ si. - p Jesu, mo ti jafara jù,
cr Ngo ṣe le fẹ Ọ b’o ti yẹ?
Em’ o ṣe le gb’ ogo Rẹ ga,
Ati ẹwà orukọ Rẹ.
f Oluwa mi, &c. - mp Jesu, kil’ o ri ninu mi,
Ti ‘fẹ na fi pọ̀ to bayi?
cr Ore Rẹ si mi ti pọ̀ to!
O ta gbogbo èro mi yọ!
f Oluwa mi, &c. - f Jesu, ‘Wọ o jẹ orin mi,
Tirẹ l’ aìya at’ ọkàn mi:
Tirẹ ni gbogbo ini mi,
Olugbala, ‘Wọ ni temi:
ff Oluwa mi, mo fẹràn Rẹ,
Jẹ ki nle ma fẹràn Rẹ si. Amin.