Skip to content
Iwe Orin Mimo

Orin 330

Jesu, kìki ironu Rẹ

Jesus, the very thought of thee

Meter C.M (8.6.8.6) Ife si Olorun
  1. mf Jesu, kìki ironu Rẹ,
    Fi ayọ̀ kún ọkàn;
    Ṣugbọn k’a ri Ọ l’o dùn jù,
    K’a simi lọdọ Rẹ.

  2. f Ẹnu kò sọ, eti kò gbọ,
    Ko ti ọkàn wá ri;
    Okọ t’o sọ̀wọn, t’o dun bi
    Ti Jesu Oluwa.

  3. p Ireti ọkàn ti nkanu,
    Olore ẹlẹṣẹ;
    cr O ṣeun f’ awọn ti nwa Ọ,
    f Awọn t’o ri Ọ yọ̀.

  4. f Ayọ̀ wọn, ẹnu kò le sọ,
    Ẹda kò le rohin;
    Ifẹ Jesu, b’o ti pọ̀ to,
    Awọn Tirẹ̀ l’o mọ̀.

  5. f Jesu, ‘Wọ ma jẹ ayọ̀ wa,
    ‘Wọ sa ni ère wa;
    Ma jẹ ogo wa nisiyi,
    Ati titi lailai. Amin.