Orin 317
Ohun ogo Rẹ l’a nrohin
Glorious things of thee are spoken
- f Ohun ogo Rẹ l’a nrohin,
Sion, ti Ọlọrun wa:
Ọrọ ẹnit’ a kò lè yẹ̀,
Ṣe ọ yẹ fun bugbe Rẹ̀.
L’ori apat’ aiyeraiye,
Kini lè mi ‘simi rẹ?
A f’ odi ‘gbala yi ọ ká,
K’ o lè ma rín ọta rẹ. - mf Wo! Ipadò omi iyè,
Nt’ifẹ Ọlọrun sun wa,
O to fun gbogbo ọmọ Rẹ̀,
Ẹru aini kò si mọ;
Tal’ o lè rẹ̀, ‘gba odo na
Ba nṣàn t’o lè pongbẹ rẹ̀?
Or’ọfẹ Olodumare
Kì yẹ̀ lat’ irandiran. - cr Ara Sion alabukun,
T’ a f’ẹjẹ Oluwa wẹ̀;
Jesu ti nwọn ti ngbẹkẹle,
Sọ wọn d’ ọba, woli Rẹ̀.
p Ṣiṣa l’ohun afẹ aiye,
Pẹlu ogo asa rẹ̀,
f Iṣura totọ at’ ayò,
Kik’ ọmọ Sion l’ o mọ. Amin.