Orin 311
Alafia, li aiye ẹ̀ṣẹ yi?
Peace, perfect peace, in this dark world of sin?
- mp Alafia, li aiye ẹ̀ṣẹ yi?
Ẹjẹ Jesu nwipe, “Alafia.” - mf Alafia, ninu ọpọ lala?
Lati ṣe ifẹ Jesu, ni ‘simi. - Alafia, n’nu ìgbi banujẹ?
L’aiya Jesu ni dakẹ rọrọ wà. - mp Alafia, gb’ ará wa wà l’ajo?
Ni ‘pamọ Jesu, ibẹru kò si. - f Alafia, b’ a kò tilẹ m’ ọla?
Ṣugbon a mọ̀ pe Jesu wà lailai. - mp Alafia, nigb’ akoko ikú?
f Olugbala wa ti ṣẹgun ikú - di O tó: jakadi aiye fẹrẹ pin,
p Jesu y’o pe wa s’ ọrun alafia. Amin.