Orin 303
Aigbagbọ, bila! Temi l’ Oluwa
Begone, unbelief; My Saviour is near
- f Aigbagbọ, bila! Temi l’ Oluwa,
On o si dide fun ìgbala mi;
Ki nsa ma gbadurà, On o ṣe rànwo:
‘Gba Krist wà lọdọ mi, ìfoiya ko si. - p B’ ọ̀na mi ba ṣu, On l’o sa ntọ́ mi,
Ki nsa gbọran ṣṣa, On o sì pèse;
Bi iranlọwọ ẹda gbogbo ṣ´aki,
Ọrọ t’ ẹnu Rẹ̀ sọ y’o bori dandan. - Ifẹ t’o nfi hàn kò jẹ ki nrò pe,
Y’o fi mi silẹ ninu wahala:
Iranwọ ti mo sì nri lojojumọ,
O nkì mi laìya pe, emi o la já. - p Emi o ṣe kùn tori ipọnju,
Tabi irora? O ti sọ tẹlẹ!
Mo m’ọ̀rọ̀ Rẹ̀ p’awọn ajogun ‘gbàla,
Nwọn kò le s’ aikọja larin wahala. - p Ẹda kò le sọ kikoro ago
T’Olugbala mu, k’ẹlẹṣẹ le yè;
Aiye Rẹ̀ tilẹ buru jù temi lọ,
Jesu ha le jìya, k’emi sì ma sa! - mf Njẹ b’ohun gbogbo ti nṣiṣẹ ire,
p Adùn n’ikorò, onjẹ li ogùn;
B’ oni tilẹ koro, sa kò ni pẹ mọ́,
ff Gbana orin ‘ṣẹgun yio ti dùn to ! Amin.