Skip to content
Iwe Orin Mimo

Orin 300

Lọ, l’orọ̀ kutukutu

Go, when the morning shineth

Meter 7.6.7.6.7.6.7.6 Adura
  1. mf Lọ, l’orọ̀ kutukutu,
    Lọ, ni ọ̀sángangan,
    Lọ, ni igba aṣalẹ,
    Lọ, ni ọganjọ oru;
    Lọ, t’ iwọ t’ inu rere,
    Gbagbe ohun aiye,
    p Si kunlẹ̀ n’ iyẹwu rẹ,
    Gbadurà nikọkọ̀,

  2. mf Ranti awọn t’ o fẹ ọ,
    At’ awọn t’ iwọ fe;
    Awọn t’o korira rẹ,
    Si gbadurà fun wọn;
    Lẹhin na, tọtọ ‘bukun
    Fun ‘wọ tikalarẹ;
    Ninu adurà re, ma
    Pe orukọ Jesu.

  3. B’ áye ati gbadura
    Nikọkọ̀ kò si si,
    T’ọkàn rẹ fẹ gbadura,
    ‘Gbat’ ọrẹ́ yi ọ ka,
    ‘Gbana, adurà jẹjẹ
    Lat’ inu ọkàn rẹ
    Y’o de ọdọ Ọlọrun,
    Ọlọrun Alanu.

  4. f Kò ọi ayọ́ kan l’aiye,
    T’ o si ju eyi lọ:
    nit’ agbara t’ a fin wa.
    Lati ma gbadura;
    p ‘Gbat’ inu rẹ ko ba dùn,
    Jẹ k’ ọkàn rẹ wolẹ̀;
    cr Ninu ayọ̀ rẹ gbogbo,
    Ranti or’ọfẹ rẹ. Amin.