Orin 297
“Tori Mi at’Ihinrere
For my sake, and the Gospel's
- f “Tori Mi at’Ihinrere,
Ẹ lọ sọ t’Iràpada;
cr Awọn onṣe Rẹ́ nke, ‘Amin’!
f Tirẹ ni gbogbo ogo;”
mf Nwọn nsọ t’ibí, t’iya, t’iku,
Ifẹ etutu nla Rẹ̀;
Nwọn kà ohun aiye s’ ofò,
f T’ ajinde on ‘jọba Rẹ̀. - f Gbọ, gbọ ipè ti Jubili,
O ndun yi gbogb’aiye ka;
cr N’ilẹ ati loju okun,
A ntàn ihin igbala,
p Bi ọjọ na ti nsunmọle,
T’ Ogun si ngbona janjan,
f Imọlẹ Ila-orùn na
ff Y’o mọ́ larin okunkun. - f Siwaju ati siwaju
Lao ma gbọ Halleluya,
cr Ijọ ajagun y’o ma yọ̀,
Pẹl’ awọn oku mimọ;
A fọ aṣọ wọn n’nu ẹjẹ,
Duru wura wọn si ndún;
ff Aiye at’ọrun d’ohùn pọ̀
Nwọn nkọ orin iṣẹgun. - f O de, Ẹnit’ a nw’ ọna Rẹ̀,
Ẹni ikẹhin na de,
Immanuẹli to d’ade,
Oluwa awọn mimọ,
cr Iye, Imọlẹ at’Ifẹ,
Mẹtalọkan titi lai;
ff Tirẹ ni Itẹ Ọlọrun
rall Ati t’Ọdọ-agutan. Amin.