Orin 292
Iwọ Ọrọ Ọlọrun
O Word of God incarnate
- f Iwọ Ọrọ Ọlọrun,
Ọgbọn at’ oké wa,
Otọ ti kì ‘yipada,
Imọlẹ aiye wa:
cr Awa yìn Ọ fun ‘mọlẹ̀
T’ inu Iwe mimọ́;
Fitila fun ẹsẹ wa,
Ti ntàn titi aiye. - mf Oluwa l’ o f’ẹbùn yi
Fun Ijọ Rẹ̀ l’ aiye;
A ngbe ‘mọlẹ̀ na soke
Lati tàn y’ aiye ka,
Apoti wura n’iṣe,
O kun fun Otitọ;
Aworan Kristi si ni,
Ọrọ iye totọ. - f O nfẹ lẹlẹ b’ asia,
T’ a ta loju ogun;
O ntàn b’ iná alore,
Si okunkun aiye;
Amọna enia ni,
p Ni wahala gbogbo,
Nin’ arin omi aiye,
cr O ntọ́ wa sọdọ Krist. - f Olugbala, ṣe ‘jọ Rẹ,
Ni fitila wura;
Lati tan imọlẹ Rẹ,
Bi aiye igbani;
Kọ́ awọn ti o ṣako,
Lati lo ‘mọlẹ yi,
Tit’ okùn aiye y’o pin,
Ti nwọn o r’oju Rẹ. Amin.