Orin 287
Ọlọrun Olodumare
Almighty God of creation
- f Ọlọrun Olodumare,
Baba, Ọmọ, Ẹmí,
Rirì ẹnit’a kò lè mọ̀,
Ẹnit’ a kò lè ri. - f Ye! Baba Olodumare,
K’ a warìri fun Ọ;
Ni gbogbo orilẹ ede,
Li a o ma sìn Ọ. - f Ọlọrun Ọmọ, Ọrẹ wa,
p ‘Wọ t’o rà w padda,
Má jọwọ wa, Olugbala!
Gbà wa patapata. - A ! Ọlọrun Ẹmi Mimọ́,
‘Wọ olore-ọfẹ;
A bẹ Ọ, fun wa ni imọ́,
K’ a m’Ọlọrun n’ ifẹ. - f Ọkanṣoṣo ṣugbọn mẹta,
Ẹniu Mẹtalọkan,
Ọlọrun awamaridi,
Ẹni Mẹtalọkan !. Amin.