Orin 280
Mimọ́, mimọ́, mimọ́ ! Olodumare!
Holy, holy, holy! Lord God Almighty!
- APA I
p Mimọ́, mimọ́, mimọ́ ! Olodumare!
mf Ni kutukutu n’iwọ o gbọ orin wa;
p Mimọ́, mimọ́, mimọ́! Oniyọnu julọ!
f Ologo mẹta lai Olubukun! - mf Mimọ́, mimọ́, mimọ́ ! awọn t’ọrun nyìn,
Nwọn nfi ade wura wọn lelẹ̀ y’itẹ ka:
cr Kerubim, Serafim nwolẹ̀ niwaju Rẹ.
f.di Wọ t’ O ti wà, t’O si wà titi la: - p Mimọ́, mimọ́, mimọ́ ! b’ okunkun pa Ọ mọ,
Bi oju ẹlẹṣẹ kò lè ri ogo Rẹ.
mf Iwọ nikan l’O mọ́, kò tun si ẹlomì,
Pipe ‘nu agbara ati n’ ifẹ. - p Mimọ́, mimọ́, mimọ́ ! Olodumare !
ff Gbogbo iṣẹ rẹ n’ ilẹ̀ l’okè l’ o nyìn Ọ;
f.cr Mimọ́, mimọ́, mimọ́ ! Oniyọnu julọ,
ff Ologo mẹta, lai Olubukun!
- p Mimọ́, mimọ́, mimọ́ ! Olodumare!
Baba, Ọmọ, Ẹmì, Ẹlẹda Oloto;
f Mimọ́, mimọ́, mimọ́ ! olododo julọ!
Pipe ‘nu ìwa, lai Olubukun. - f Mimọ́, mimọ́, mimọ́ ! gbogbo aiye gberin,
Kọrin ‘yìn; k’ aiye yin Ẹni Mẹtalọkan,
f Ọlọrun Alagbara, Ọlọrun Olufẹ,
Olupamọra, Olore ọfẹ. - f Mimọ́, mimọ́, mimọ́ ! Yọ̀, ẹni rapada,
Da ohun nyin pọ̀ mọ t’awọn ti nyin l’ ọrun;
ff Titi lai ni k’ẹ yin; “Mimọ́, mimọ́, mimọ́!”
F’ Ẹni Mẹtalọkan aiyeraiye. - p Mimọ́, mimọ́, mimọ́ ! Olodumare!
Ogo, Ọla, Ọgbọn, Agbara ni Tirẹ;
ff Mimọ́ fun Ẹni Mimọ́ ti o gunwá,
cr “Ẹlẹru ni iyin, Ẹni yanu”. Amin.