Orin 272
Wa, Parakliti mimọ
Come, Thou Holy Paraclete
- mp Wa, Parakliti mimọ,
Lat’ ibugbe Rẹ ọrun,
cr Rán itanṣan ‘mọlẹ wa. - mf Baba talaka, wá ‘hin,
Olufunni l’ẹbun, wá
Imọlẹ ọkàn, jọ wá. - p Wọ n’isimi n’nu lala,
Iboji ninu oru,
Itunu ninu ‘pọnju. - mf Wọ ‘mọlẹ t’o mọ gara,
cr Tàn sinu aiya awọn
Enia Rẹ olòtọ. - Laisi Rẹ, kil’ ẹda jẹ?
Iṣẹ at’ èro mimọ,
Lat’ ọdọ Rẹ wa ni nwọn. - p Eleri, sọ di mimọ,
Agbọgbẹ, má ṣai wo sàn,
Alaileso, mu s’eso. - Mu ọkàn tutù gbona,
M’ alagidi tẹriba
Fa aṣako wá jẹjẹ. - cr F’Ẹmi ‘jinlẹ Rẹ meje,
Kún awọn olotọ Rẹ,
F’agbara Rẹ ṣ’abo wọn. - f Rán or’ọfẹ Rẹ sihin,
Ẹkún igbala l’aiye,
At’ alafia l’ọrun. Amin.