Orin 269
Ẹmi Mimọ́ sọkale
Thou Holy Spirit, come down
- mf Ẹmi Mimọ́ sọkale,
Fi ohun ọrun han;
K’ o mu imọlẹ w’aiye,
Si ara enia,
K’ awa t’a wà l’ okunkún,
Ki o le ma riran,
p ‘Tori Jesu Kristi kú
Fun gbogbo enia. - K’o fi hàn pe ẹlẹṣẹ
Ni emi nṣe papa;
K’emi k’o le gbẹkẹ mi
Le Olugbala mi,
Nigbati a wẹ̀ mi nù
Kuro ninu ẹṣẹ,
Emi o lè fi ogo
Fun Ẹni-mimọ́ na. - f K’ o mu mi ṣe afẹri
Lati tọ Jesu lọ;
K’o jọba ni ọkàn mi,
K’o sọ mi di mimọ̀;
Ki ara ati ọkàn,
K’o dapọ lati sìn
Ọlọrun Ẹni-Mimọ́,
Mẹtalọkanṣoṣo. Amin.