Skip to content
Iwe Orin Mimo

Orin 267

Ẹmi Ẹlẹda, nipa Rẹ

Creator Spirit, by Whose aid

Meter 8.8.8.8.8.8 Ojo Isimi Funfun
  1. mf Ẹmi Ẹlẹda, nipa Rẹ
    L’a f’ipilẹ aiye sọlẹ,
    p Maṣai bẹ̀ gbogbo ọkàn wò,
    Fi ayọ Rẹ si ọkàn wa;
    Yọ wa nin’ ẹṣẹ at’ egbe,
    K’ o fi wa ṣe ibugbe Rẹ.

  2. f Orisun imọlẹ ni Ọ,
    Ti Baba ti ọe ileri;
    Iwọ Ina mimọ ọrun,
    Fi ‘fẹ ọrun kun ọkàn wa;
    p Jọ tu ororo mimọ Rẹ
    Sori wa bi a ti nkọrin.

  3. mp Da ọ̀pọ ore-ọfẹ Rẹ,
    Lat’ ọrun sori gbogbo wa;
    cr Jẹ k’a gba otitẹ Rẹ gbọ,
    K’a si ma ṣa rò l’ọkàn wa;
    F’ ara Rẹ hàn wa k’ a le ri
    Baba at’Ọmọ ninu Rẹ.

  4. f K’a fi ọla ati iyìn
    Fun Baba Olodumare;
    K’a yìn okọ Jesu logo,
    Ẹnit’ o kú lati gbà wa;
    Iyin bakanna ni fun Ọ,
    Parakliti Aiyeraiye. Amin.