Orin 265
Gbani t’ Ọlọrun sọkalẹ
When God of old came down from heaven
- f Gbani t’ Ọlọrun sọkalẹ,
O wá ni ibinu;
Ará sì nsan niwaju Rẹ̀,
Okunkun on ina. - p Nigbat’ o wá nigba keji,
O wá ninu ifẹ;
pp Ẹmi Rẹ̀ sì ntù ni lara,
B’ afẹfẹ owurọ̀. - f Iná Sinài ijọ kini,
T’ọwọ rẹ̀ mbù soke,
mp Sọkalẹ jẹjẹ bi ade,
Si ori gbogbo wọn. - f Bi ohùn ẹ̀ru na ti dún,
L’eti Israeli,
Ti nwọn si gbọ iró ipè,
To m’ohùn angẹl gbọ̀n. - mf Bẹ gẹgẹ nigbat’ Ẹmi wá
Bà le awọn Tirẹ̀,
cr Iró kan si ti ọrun wa,
Iró iji lile. - f O nkun Ijọ Jesu, o nkun
Aiye ẹsẹ yika;
mp L’ọkàn alaigbọràn nikan
Ni àye kò si fun. - mf Wa, Ọgbọn, Ifẹ, at’ Ipa,
Mu ki eti wa ṣí;
p K’a má sọ akoko wa nù;
Ki ‘fẹ Rẹ le gbà wa. Amin.