Orin 250
Ile ‘bukun kan wà
There is a blessèd home
- mf Ile ‘bukun kan wà
Lẹhin aiye wa yi,
Wahala, irora,
At’ẹkún ki dé bẹ̀;
cr Igbagbọ y’o dopin,
Ao de ‘reti l’ade,
f Imọlẹ ailopin
Ni gbogbo ibẹ̀ jẹ. - mp Ilẹ kan si tun mbẹ,
Ilẹ alafia,
cr Awọn Angẹl rere
Nkọrin n’nu rẹ̀ lailai;
ff Y’itẹ ogo Rẹ̀ ka
L’awọn ẹgbẹ mimọ
Nwolẹ, nwọn ntẹriba
F’ Ẹni Mẹtalọkan. - mf Ayọ wọn ti pọ̀ to!
p Awọn to ri Jesu
cr Nibit’ o gbe gúnwà
T’a si nfi ogo fun;
f Nwọn nkọrin iyìn Rẹ̀
Ati t’ iṣẹgun Rẹ̀,
Nwọn kò dẹkun rohin
Ohun nla t’o ti ṣe. - mf W’ oke, ẹnyin mimọ,
Ẹ lé ibẹru lọ
p Ọna hihá kanna
L’Olugbala ti gbà:
cr Ẹ fi suru duro
Fun igba die ṣa,
f T’ẹ̀rín-t’ẹ̀rín l’On o
Fi gbà nyin sọọ Rẹ̀. Amin.