Orin 25
Ọjọ ‘simi at’ ayọ̀
O day of rest and gladness
- f Ọjọ ‘simi at’ ayọ̀,
Ọjọ inu didun,
mf Ogùn fun ibanujẹ
Ọjọ dida julọ;
Ti awọn ẹni giga
Niwaju itẹ Rẹ
p Nkọ mimọ́, mimọ́, mimọ́,
S’ ẹni Mẹtalọkan. - f L’ ọjọ yi ni ‘mọlẹ là,
Nigba didà aiye:
Ati fun igbala wa
Kristi jinde loni:
mf L’ ọjọ oni l’ Oluwa
Ran Ẹmi t’ ọrun wà;
Ọjọ ologo julọ
T’ o ni ‘mọlẹ pipe. - mf Orisun ‘tura ni Ọ,
L’ aiye aginju yi:
L’ ori Rẹ, bi ni Pisga
L’ a nwo ‘lè ileri.
Ọjọ ironu didùn
Ọjo ifẹ mimọ́,
Ọjọ ajinde, lati
Aiye, si nkan ọrun. - mp L’ oni s’ ilu t’ arẹ̀ mu
Ni Manna t’ ọrun bò;
f Si ipejọpọ mimọ
N’ ipè fadaka ndùn.
Nibiti Ihin-rere
Ntàn imọlẹ̀ mimọ́,
p Omi ìye nṣan jẹjẹ
Ti ntù ọkàn lara. - K’ a r’ ore-ọfẹ titun
L’ ọjọ ‘simi wa yi,
K’ a si dé ‘simi t’ o kù
F’ awọn alabukun.
f Nibẹ k’ a gbohun soke
Si Baba at’ Ọmọ
Ati si Ẹmi Mimọ,
N’ iyin Mẹtalọkan. Amin