Orin 248
O ti lọ. Awọsanma
He is gone—a cloud of light
- p O ti lọ. Awọsanma,
Ti gba kuro loju wa,
f Soke ọrun nibiti
Oju wa kò le tẹle;
O ti kuro l’aiye yi,
O ti de ibi mimẹ,
Lala at’ irora tan,
Ijà tan, o ti ṣẹgun. - p O ti lọ. Awa sì wá
L’aiye ẹṣẹ at’ iku;
A ni ‘ṣẹ́ lati ṣe fun,
L’aiye t’o ti fisilẹ,
cr K’a si tẹle ọna Rẹ̀;
K’a tẹle tọkàntọkan
K’a s’ọta Rẹ di ọrẹ,
K’a fi Krist hàn n’iwa wa. - p O ti lọ. On ti wipe,
“O dara ki Emi lọ,”
Ni ara ṣa l’o yà wa,
Ṣugbọn or’ọfẹ Rẹ̀ wa:
mf On ni awa kò ri mọ,
A ni Olutunu rẹ̀,
f Ẹmi Rẹ̀ si jẹ tiwa.
O ns’ agbara wa d’ọtun. - p O ti lọ. L’ọna kanna,
L’o yẹ k’ Ijọ Rẹ̀ ma lọ;
f K’a gbagbe ohun ẹ̀hin,
K’a si ma tẹ̀ siwaju:
Ọrọ Rẹ̀ ni ‘mọlẹ wa,
Titi de opin aiye,
Nibiti otọ Rẹ̀ wà,
Y’o pese fun alaini. - p O ti lọ. Lẹkan si i
A o tun f’ oju wa ri;
f O wà bakanna l’ọrun,
Gẹgẹ b’o ti wà l’aiye:
N’nu ‘bugbe t’o wà nibẹ,
Y’o pese àye fun wa,
p Ninu aiye ti mbọ̀ wa,
A o j’ọkan pẹlu Rẹ̀. - p O ti lọ. Fun ire wa,
Ẹ jẹ ki a duro dè;
f O jinde, ko si nihin.
O ti goke re ọrun;
Jẹ k’a gb’ ọkan wa soke,
Sibiti Jesu ti lọ,
ff Si ọdọ Ọlọrun wa,
Nibẹ l’alafia wà. Amin.