Orin 243
Kristi, lẹhin iṣẹgun
O Christ, thou hast ascended
- f Kristi, lẹhin iṣẹgun,
Iwọ ti goke lọ;
Kerub at’ ogun-ọrun
Wá sìn Ọ goke lọ.
mf K’aiye sọ ‘tàn na jade—
cr Emmanuel wa,
f Ti ṣ’ara iy’ ara wa,
G’ ori itẹ Baba. - mf Nibẹ l’ o duro, t’ o nsọ
di Agbara ẹjẹ Rẹ;
O mbẹbẹ fun ẹ̀lẹṣẹ,
‘Wọ Alagbawi wa.
p Gbogbo ayidayida
T’ ayọ̀, t’ aniyan wa,
cr N’ iwọ nṣe iyọ́nu si,
T’ iwọ si mbẹbẹ fun. - p Nitori itoye nla
Ti agbelebu Rẹ,
K’ o fi Ẹmi Rẹ fun wa,
Sọ òfo wa d’ère.
Titi nipa iyanju,
Ọkàn wa o gòke;
Lati ba Ọ gbe titi,
Li ayọ̀ ailopin. Amin.