Orin 241
Wo Aṣẹgun b’o ti gòke
See, the Lord ascends in triumph
- Wo Aṣẹgun b’o ti gòke,
Wò Ọba n’nu ọla Rẹ̀,
O gùn kẹkẹ ofurufu
Lọ sọrun agbala Rẹ̀;
Gbọ orin awọn Angẹli,
Halleluya ni nwọn nkọ,
Awọn ‘lẹkun si ṣi silẹ,
Lati gbà Ọba ọrun. - mf Tani Ologo ti mbọ yi,
T’on ti ipè jubeli?
p Oluwa awọn ‘mọ-ogun,
On to ti ṣẹgun fun wa,
p O jiya lor’ agbelebu,
O jinde ninu oku,
f O ṣẹgun Eṣu at’ ẹ̀ṣẹ,
Ati gbogbo ọta Rẹ̀. - mf B’o ti nbuk’ awọn ọ̀rẹ́ Rẹ̀,
A gba kuro lọwọ wọn;
Bi oju nwọn si ti nwo lọ.
O nù nin’ awọsanma;
Ẹnit’o ba Ọlọrun rìn,
T’o si nwasu otitọ,
On, Eẹọku wa, l’a gbe lọ
S’ile Rẹ̀ loke ọrun. - mp On, Aarọn wa, gbé ẹjẹ Rẹ̀
Wọ̀ inu ikele lọ,
Jọṣua wa, ti wọ̀ Kenaan,
Awon oba nwariri;
mf A fi di ẹya Israel
Mulẹ nibi simi wọn
Ẹlija wa si fẹ fun wa
N ilọpo meji Ẹmi - f Iwọ ti gbe ara wọ̀
Lọ s` ọw’ ọtun Ọlorun,
A si joko nibi giga
Pẹlu Rẹ ninu ogo ;
ff Awọn Angẹli mbọ jesu,
Enia joko lor’ itẹ,
Oluwa, b’ Iwọ ti goke,
Jọ jẹ k’a le goke bẹ. Amin.